I. Joh 4:13-16

I. Joh 4:13-16 YBCV

Nipa eyi li awa mọ̀ pe awa ngbé inu rẹ̀, ati on ninu wa, nitoriti o ti fi Ẹmí rẹ̀ fun wa. Awa ti ri, a si jẹri, pe Baba rán Ọmọ rẹ̀ lati jẹ́ Olugbala fun araiye. Ẹnikẹni ti o ba jẹwọ pe Jesu Ọmọ Ọlọrun ni, Ọlọrun ngbé inu rẹ̀, ati on ninu Ọlọrun. Awa ti mọ̀, a si gbà ifẹ ti Ọlọrun ní si wa gbọ́. Ifẹ ni Ọlọrun; ẹniti o ba si ngbé inu ifẹ o ngbé inu Ọlọrun, ati Ọlọrun ninu rẹ̀.