Ṣugbọn ẹniti o ba ni ohun ini aiye, ti o si ri arakunrin rẹ̀ ti iṣe alaini, ti o si sé ilẹkun ìyọ́nu rẹ̀ mọ ọ, bawo ni ifẹ Ọlọrun ti ngbé inu rẹ̀? Ẹnyin ọmọ mi, ẹ máṣe jẹ ki a fi ọrọ tabi ahọn fẹran, bikoṣe ni iṣe ati li otitọ. Ati nipa eyi li awa ó mọ̀ pe awa jẹ ti otitọ, ati pe awa o si dá ara wa loju niwaju rẹ̀, Ninu ohunkohun ti ọkàn wa ba ndá wa lẹbi; nitoripe Ọlọrun tobi jù ọkàn wa lọ, o si mọ̀ ohun gbogbo. Olufẹ, bi ọkàn wa kò ba dá wa lẹbi, njẹ awa ni igboiya niwaju Ọlọrun. Ati ohunkohun ti awa ba bère, awa nri gbà lọdọ rẹ̀, nitoriti awa npa ofin rẹ̀ mọ́, awa si nṣe nkan wọnni ti o dara loju rẹ̀. Eyi si li ofin rẹ̀, pe ki awa ki o gbà orukọ Jesu Kristi Ọmọ rẹ̀ gbọ́, ki a si fẹràn ara wa, gẹgẹ bi o ti fi ofin fun wa. Ẹniti o ba si pa ofin rẹ̀ mọ́ ngbé inu rẹ̀, ati on ninu rẹ̀. Ati nipa eyi li awa mọ̀ pe o ngbé inu wa, nipa Ẹmí ti o fifun wa.
Kà I. Joh 3
Feti si I. Joh 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Joh 3:17-24
12 Days
Everyone wants to know what true love is. But few people look at what the Bible says about love. Love is one of the central themes of Scripture and the most essential virtue of the Christian life. This plan from Thistlebend Ministries explores the biblical meaning of love and how to love God better and love others.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò