I. Joh 2:24-28

I. Joh 2:24-28 YBCV

Ṣugbọn ẹnyin, ki eyini ki o mã gbe inu nyin, ti ẹnyin ti gbọ́ li àtetekọṣe. Bi eyiti ẹnyin ti gbọ́ li àtetekọṣe ba ngbe inu nyin, ẹnyin ó si duro pẹlu ninu Ọmọ ati ninu Baba. Eyi si ni ileri na ti o ti ṣe fun wa, ani ìye ainipẹkun. Nkan wọnyi ni mo kọwe si nyin niti awọn ti ntàn nyin jẹ. Ṣugbọn ìfororó-yàn ti ẹnyin ti gbà lọwọ rẹ̀, o ngbe inu nyin, ẹnyin kò si ni pe ẹnikan nkọ́ nyin: ṣugbọn ìfororó-yàn na nkọ́ nyin li ohun gbogbo ti o jẹ otitọ, ti kì si iṣe èké, ani gẹgẹ bi o si ti kọ́ nyin, ẹ mã gbe inu rẹ̀. Ati nisisiyi, ẹnyin ọmọ mi, ẹ mã gbe inu rẹ̀; pe, nigbati on o ba farahàn, ki a le ni igboiya niwaju rẹ̀, ki oju má si tì wa niwaju rẹ̀ ni igba wiwá rẹ̀.