Ẹnyin ọmọ mi, igba ikẹhin li eyi: bi ẹnyin si ti gbọ́ pe Aṣodisi-Kristi mbọ̀wá, ani nisisiyi Aṣodisi-Kristi pupọ̀ ni mbẹ; nipa eyiti awa fi mọ̀ pe igba ikẹhin li eyi. Nwọn ti ọdọ wa jade, ṣugbọn nwọn ki iṣe ará wa; nitori nwọn iba ṣe ará wa, nwọn iba bá wa duro: ṣugbọn nwọn jade ki a le fi wọn hàn pe gbogbo nwọn ki iṣe ará wa. Ṣugbọn ẹnyin ni ifororo-yan lati ọdọ Ẹni Mimọ́ nì wá, ẹnyin si mọ̀ ohun gbogbo. Emi kò kọwe si nyin nitoripe ẹnyin kò mọ̀ otitọ, ṣugbọn nitoriti ẹnyin mọ̀ ọ, ati pe kò si eke ninu otitọ. Tani eke, bikoṣe ẹniti o ba sẹ́ pe Jesu kì iṣe Kristi? Eleyi ni Aṣodisi-Kristi, ẹniti o ba sẹ́ Baba ati Ọmọ. Ẹnikẹni ti o ba sẹ́ Ọmọ, on na ni kò gbà Baba: ṣugbọn ẹniti o ba jẹwọ Ọmọ, o gbà Baba pẹlu. Ṣugbọn ẹnyin, ki eyini ki o mã gbe inu nyin, ti ẹnyin ti gbọ́ li àtetekọṣe. Bi eyiti ẹnyin ti gbọ́ li àtetekọṣe ba ngbe inu nyin, ẹnyin ó si duro pẹlu ninu Ọmọ ati ninu Baba. Eyi si ni ileri na ti o ti ṣe fun wa, ani ìye ainipẹkun. Nkan wọnyi ni mo kọwe si nyin niti awọn ti ntàn nyin jẹ. Ṣugbọn ìfororó-yàn ti ẹnyin ti gbà lọwọ rẹ̀, o ngbe inu nyin, ẹnyin kò si ni pe ẹnikan nkọ́ nyin: ṣugbọn ìfororó-yàn na nkọ́ nyin li ohun gbogbo ti o jẹ otitọ, ti kì si iṣe èké, ani gẹgẹ bi o si ti kọ́ nyin, ẹ mã gbe inu rẹ̀.
Kà I. Joh 2
Feti si I. Joh 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Joh 2:18-27
21 Days
In the 21 Days to Overflow YouVersion plan, Jeremiah Hosford will take readers on a 3-week journey of emptying themselves of themselves, being filled with the Holy Spirit, and living out an overflowing, Spirit-filled life. It’s time to stop living normally and start living an overflowing life!
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò