I. Kor 9:8-12

I. Kor 9:8-12 YBCV

Emi ha nsọ̀rọ nkan wọnyi bi enia? tabi ofin kò wi bakanna pẹlu bi? Nitoriti a ti kọ ọ ninu ofin Mose pe, Iwọ kò gbọdọ pa malu ti npaka li ẹnu mọ́. Iha ṣe malu li Ọlọrun nṣe itọju bi? Tabi o nsọ eyi patapata nitori wa? Nitõtọ nitori wa li a ṣe kọwe yi: ki ẹniti ntulẹ ki o le mã tulẹ ni ireti; ati ẹniti npakà, ki o le ni ireti ati ṣe olubapin ninu rẹ̀. Bi awa ba ti funrugbin ohun ti ẹmí fun nyin, ohun nla ha ni bi awa ó ba ká ohun ti nyin ti iṣe ti ara? Bi awọn ẹlomiran ba ṣe alabapin ninu agbara yi lori nyin, awa kọ́ ẹniti o tọ́ fun ju? Ṣugbọn awa kò lò agbara yi; ṣugbọn awa farada ohun gbogbo, ki awa ki o má ba ṣe ìdena fun ihinrere Kristi.