I. Kor 9:25-27

I. Kor 9:25-27 YBCV

Ati olukuluku ẹniti njijàdu ati bori a ma ni iwọntunwọnsi ninu ohun gbogbo. Njẹ nwọn nṣe e lati gbà adé idibajẹ; ṣugbọn awa eyi ti ki idibajẹ. Nitorina bẹ̃ni emi nsáre, kì iṣe bi ẹniti kò da loju; bẹ̃ni emi njà, ki iṣe bi ẹnikan ti nlu afẹfẹ: Ṣugbọn emi npọn ara mi loju, mo si nmu u wá sabẹ itẹriba: pe lẹhin ti mo ti wasu fun awọn ẹlomiran, nitori ohunkohun, ki emi tikarami máṣe di ẹni itanù.