I. Kor 7:20-24

I. Kor 7:20-24 YBCV

Ki olukuluku enia duro ninu ìpe nipasẹ eyi ti a ti pè e. A ha pè ọ, nigbati iwọ jẹ ẹrú? máṣe kà a si: ṣugbọn bi iwọ ba le di omnira, kuku ṣe eyini. Nitori ẹniti a pè ninu Oluwa, ti iṣe ẹrú, o di ẹni omnira ti Oluwa: gẹgẹ bẹ̃ li ẹniti a pè ti o jẹ omnira, o di ẹrú Kristi. A ti rà nyin ni iye kan; ẹ máṣe di ẹrú enia. Ará, ki olukuluku enia, ninu eyi ti a pè e, ki o duro ninu ọkanna pẹlu Ọlọrun.