I. Kor 7:13-14

I. Kor 7:13-14 YBCV

Ati obinrin ti o ni ọkọ ti kò gbagbọ́, bi inu rẹ̀ ba si dùn lati mã ba a gbé, ki on máṣe fi i silẹ. Nitoriti a sọ alaigbagbọ́ ọkọ na di mimọ́ ninu aya rẹ̀, a si sọ alaigbagbọ́ aya na di mimọ́ ninu ọkọ rẹ̀: bikoṣe bẹ̃ awọn ọmọ nyin iba jẹ alaimọ́; ṣugbọn nisisiyi nwọn di mimọ́.