I. Kor 7:1-3

I. Kor 7:1-3 YBCV

NJẸ niti awọn ohun ti ẹ ti kọwe: O dara fun ọkunrin ki o má fi ọwọ kàn obinrin. Ṣugbọn nitori àgbere, ki olukuluku ki o ni aya tirẹ̀, ati ki olukuluku ki o si ni ọkọ tirẹ̀. Ki ọkọ ki o mã ṣe ohun ti o yẹ si aya: bẹ̃ gẹgẹ si li aya pẹlu si ọkọ.