I. Kor 6:12-17

I. Kor 6:12-17 YBCV

Ohun gbogbo li o yẹ fun mi, ṣugbọn ki iṣe ohun gbogbo li o li ère: ohun gbogbo li o yẹ fun mi, ṣugbọn emi kì yio jẹ ki a fi mi sabẹ agbara ohunkohun. Onjẹ fun inu, ati inu fun onjẹ: ṣugbọn Ọlọrun yio fi opin si ati inu ati onjẹ. Ṣugbọn ara kì iṣe ti àgbere, bikoṣe fun Oluwa; ati Oluwa fun ara. Ṣugbọn Ọlọrun ti jí Oluwa dide, yio si jí awa dide pẹlu nipa agbara rẹ̀. Ẹnyin kò mọ̀ pe ẹ̀ya-ara Kristi li ara nyin iṣe? njẹ emi o ha mu ẹ̀ya-ara Kristi, ki emi ki o si fi ṣe ẹ̀ya-ara àgbere bi? ki a má ri. Tabi, ẹnyin kò mọ̀ pe ẹniti o ba dàpọ mọ́ àgbere di ara kan? nitoriti o wipe, Awọn mejeji ni yio di ara kan. Ṣugbọn ẹniti o dàpọ mọ́ Oluwa di ẹmí kan.