A nròhin rẹ̀ kalẹ pe, àgbere wà larin nyin, ati irú àgbere ti a kò tilẹ gburo rẹ̀ larin awọn Keferi, pe ẹnikan ninu nyin fẹ aya baba rẹ̀. Ẹnyin si nfẹ̀ soke, ẹnyin kò kuku kãnu ki a le mu ẹniti o hu iwa yi kuro larin nyin. Nitori lõtọ, bi emi kò ti si lọdọ nyin nipa ti ara, ṣugbọn ti mo wà pẹlu nyin nipa ti ẹmí, mo ti ṣe idajọ ẹniti o hu iwà yi tan, bi ẹnipe mo wà lọdọ nyin. Li orukọ Jesu Kristi Oluwa wa. Nigbati ẹnyin ba pejọ, ati ẹmí mi, pẹlu agbara Jesu Kristi Oluwa wa, Ki ẹ fi irú enia bẹ̃ le Satani lọwọ fun iparun ara, ki a le gbà ẹmí là li ọjọ Jesu Oluwa. Iṣeféfe nyin kò dara. Ẹnyin kò mọ̀ pe iwukara diẹ ni imu gbogbo iyẹfun di wiwu? Nitorina ẹ mu iwukara atijọ kuro ninu nyin, ki ẹnyin ki o le jẹ́ iyẹfun titun, gẹgẹ bi ẹnyin ti jẹ́ aiwukara. Nitori a ti fi irekọja wa, ani Kristi, rubọ fun wa.
Kà I. Kor 5
Feti si I. Kor 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Kor 5:1-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò