I. Kor 4:7-14

I. Kor 4:7-14 YBCV

Nitori tali o mu ọ yàtọ? kini iwọ si ní ti iwọ kò ti gbà? njẹ bi iwọ ba si ti gbà a, éhatiṣe ti iwọ fi nhalẹ, bi ẹnipe iwọ kò gbà a? A sá tẹ́ nyin lọrùn nisisiyi, a sá ti sọ nyin di ọlọrọ̀ nisisiyi, ẹnyin ti njọba laisi wa: iba si wu mi ki ẹnyin ki o jọba, ki awa ki o le jùmọ jọba pẹlu nyin. Nitori mo rò pe Ọlọrun ti yan awa Aposteli kẹhin bi awọn ẹniti a dalẹbi ikú: nitoriti a fi wa ṣe iran wò fun aiye, ati fun angẹli, ati fun enia. Awa jẹ aṣiwere nitori Kristi, ṣugbọn ẹnyin jẹ ọlọgbọ́n ninu Kristi; awa jẹ alailera, ṣugbọn ẹnyin jẹ alagbara; ẹnyin jẹ ọlọlá, ṣugbọn awa jẹ ẹni ẹ̀gan. Ani titi fi di wakati yi li ebi npa wa, ti òrungbẹ si ngbẹ wa, ti a si wà ni ìhoho, ti a si nlù wa, ti a kò si ni ibugbé kan; Ti a nṣe lãlã, a nfi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ: nwọn ngàn wa, awa nsure; nwọn nṣe inunibini si wa, awa nforitì i: Nwọn nkẹgàn wa, awa mbẹ̀bẹ: a ṣe wa bi ohun ẹgbin aiye, bi ẽri ohun gbogbo titi di isisiyi. Emi kò kọ̀we nkan wọnyi lati fi dojutì nyin, ṣugbọn lati kìlọ fun nyin bi awọn ọmọ mi ayanfẹ.