I. Kor 3:9-11

I. Kor 3:9-11 YBCV

Nitori alabaṣiṣẹpọ pẹlu Ọlọrun li awa: ọgbà Ọlọrun ni nyin, ile Ọlọrun ni nyin. Gẹgẹ bi ore-ọfẹ Ọlọrun ti a fifun mi, bi ọlọ́gbọn ọ̀mọ̀lé, mo ti fi ipilẹ sọlẹ, ẹlomiran si nmọ le e. Ṣugbọn ki olukuluku kiyesara bi o ti nmọ le e. Nitori ipilẹ miran ni ẹnikan kò le fi lelẹ jù eyiti a ti fi lelẹ lọ, ti iṣe Jesu Kristi.