I. Kor 2:4-6

I. Kor 2:4-6 YBCV

Ati ọ̀rọ mi, ati iwasu mi kì iṣe nipa ọ̀rọ ọgbọ́n enia, ti a fi nyi ni lọkàn pada, bikoṣe nipa ifihan ti Ẹmí ati ti agbara: Ki igbagbọ́ nyin ki o máṣe duro ninu ọgbọ́n enia, bikoṣe ninu agbara Ọlọrun. Ṣugbọn awa nsọ̀rọ ọgbọ́n larin awọn ti o pé: ṣugbọn kì iṣe ọgbọ́n ti aiye yi, tabi ti awọn olori aiye yi, ti o di asan