I. Kor 16:19-24

I. Kor 16:19-24 YBCV

Awọn ijọ ni Asia kí nyin. Akuila ati Priskilla kí nyin pupọ ninu Oluwa, pẹlu ijọ ti o wà ni ile wọn. Gbogbo awọn arakunrin kí nyin. Ẹ fi ifẹnukonu mimọ́ kí ara nyin. Ikíni ti emi Paulu, lati ọwọ́ emi tikarami wá. Bi ẹnikẹni kò ba fẹ Jesu Kristi Oluwa, ẹ jẹ ki o di Anatema. Maranata. Õre-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa ki o pẹlu nyin. Ifẹ mi wà pẹlu gbogbo nyin ninu Kristi Jesu. Amin.