I. Kor 16:15-18

I. Kor 16:15-18 YBCV

Njẹ mo bẹ nyin, ará (ẹ sá mọ̀ ile Stefana, pe awọn ni akọso Akaia, ati pe, nwọn si ti fi ara wọn fun iṣẹ-iranṣẹ awọn enia mimọ́), Ki ẹnyin ki o tẹriba fun irú awọn bawọnni, ati fun olukuluku olubaṣiṣẹ pọ̀ pẹlu wa ti o si nṣe lãla. Mo yọ̀ fun wíwa Stefana ati Fortunatu ati Akaiku: nitori eyi ti o kù nipa tinyin nwọn ti fi kún u. Nitoriti nwọn tù ẹmí mi lara ati tinyin: nitorina ẹ mã gbà irú awọn ti o ri bẹ̃.