I. Kor 16:10-14

I. Kor 16:10-14 YBCV

Njẹ bi Timotiu ba de, ẹ jẹ́ ki o wà lọdọ nyin laibẹ̀ru: nitori on nṣe iṣẹ Oluwa, bi emi pẹlu ti nṣe. Nitorina ki ẹnikẹni máṣe kẹgan rẹ̀. Ṣugbọn ẹ sìn i jade lọna-ajò li alafia, ki on ki o le tọ̀ mi wá: nitoriti emi nwò ọ̀na rẹ̀ pẹlu awọn arakunrin. Ṣugbọn niti Apollo arakunrin wa, mo bẹ ẹ pupọ ki o tọ̀ nyin wá pẹlu awọn arakunrin: ṣugbọn kì iṣe ifẹ rẹ̀ rara lati wá nisisiyi; ṣugbọn on o wá nigbati o ba ni akokò ti o wọ̀. Ẹ mã ṣọra, ẹ duro gangan ni igbagbọ́, ẹ ṣe bi ọkunrin, ẹ jẹ alagbara. Ẹ mã fi ifẹ ṣe gbogbo nkan nyin.