NJẸ niti idawo fun awọn enia mimọ́, bi mo ti fi aṣẹ fun awọn ijọ Galatia, bẹ̃ gẹgẹ ni ki ẹ ṣe. Li ọjọ ikini ọ̀sẹ, ki olukuluku nyin fi sinu iṣura lọdọ ara rẹ̀ li apakan, gẹgẹ bi Ọlọrun ti ṣe rere fun u, ki o máṣe si ikojọ nigbati mo ba de. Ati nigbati mo ba de, ẹnikẹni ti ẹ ba fi iwe nyin yàn, awọn li emi ó rán lati mu ẹ̀bun nyin gòke lọ si Jerusalemu. Bi o ba si yẹ ki emi ki o lọ pẹlu, nwọn ó si ba mi lọ. Ṣugbọn emi o tọ̀ nyin wá, nigbati emi ba ti kọja lọ larin Makedonia: nitori emi ó kọja larin Makedonia. Boya emi ó si duro, ani, emi a si lo akoko otutu pẹlu nyin, ki ẹnyin ki o le sìn mi li ọ̀na àjo mi, nibikibi ti mo ba nlọ.
Kà I. Kor 16
Feti si I. Kor 16
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Kor 16:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò