I. Kor 15:3-9

I. Kor 15:3-9 YBCV

Nitoripe ṣiwaju ohun gbogbo mo fi eyiti emi pẹlu ti gbà le nyin lọwọ, bi Kristi ti kú nitori ẹ̀ṣẹ wa gẹgẹ bi iwe-mimọ́ ti wi; Ati pe a sinkú rẹ̀, ati pe o jinde ni ijọ kẹta gẹgẹ bi iwe-mimọ́ ti wi: Ati pe o farahan Kefa, lẹhin eyini awọn mejila: Lẹhin eyini o farahan awọn ará ti o jù ẹ̃dẹgbẹta lọ lẹkanna; apakan ti o pọ̀ju ninu wọn wà titi fi di isisiyi, ṣugbọn awọn diẹ ti sùn. Lẹhin eyini o farahan Jakọbu; lẹhinna fun gbogbo awọn Aposteli. Ati nikẹhin gbogbo wọn o farahàn mi pẹlu, bi ẹni ti a bí ṣiwaju akokò rẹ̀. Nitori emi li ẹniti o kere jùlọ ninu awọn Aposteli, emi ẹniti kò yẹ ti a ba pè li Aposteli, nitoriti mo ṣe inunibini si ijọ enia Ọlọrun.