Ṣugbọn iba wu mi ki gbogbo nyin le mã sọ oniruru ède, ṣugbọn ki ẹ kuku mã sọtẹlẹ: nitori ẹniti nsọtẹlẹ pọ̀ju ẹniti nsọ oniruru ède lọ, ayaṣebi o ba nṣe itumọ̀, ki ijọ ki o le kọ́ ẹkọ́. Njẹ nisisiyi, ará, bi mo ba wá si arin nyin, ti mo si nsọrọ li ede aimọ̀, ère kili emi o jẹ fun nyin, bikoṣepe mo ba mba nyin sọrọ, yala nipa iṣipaya, tabi nipa imọ̀, tabi nipa isọtẹlẹ, tabi nipa ẹkọ́? Bẹni pẹlu awọn nkan ti kò li ẹmí ti ndún, ibã ṣe fère tabi dùru, bikoṣepe ìyatọ ba wà ninu ohùn wọn, a ó ti ṣe mọ̀ ohun ti fère tabi ti dùru nwi? Nitoripe bi ohùn ipè kò ba daju, tani yio mura fun ogun? Bẹ̃ si li ẹnyin, bikoṣepe ẹnyin ba nfi ahọ́n nyin sọrọ ti o ye ni, a o ti ṣe mọ̀ ohun ti a nwi? nitoripe ẹnyin o sọ̀rọ si ofurufu. O le jẹ pe oniruru ohùn ni mbẹ li aiye, kò si si ọ̀kan ti kò ni itumọ. Njẹ bi emi kò mọ̀ itumọ ohùn na, emi o jasi alaigbede si ẹniti nsọ̀rọ, ẹniti nsọ̀rọ yio si jasi alaigbede si mi.
Kà I. Kor 14
Feti si I. Kor 14
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Kor 14:5-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò