I. Kor 14:37-40

I. Kor 14:37-40 YBCV

Bi ẹnikẹni ba ro ara rẹ̀ pe on jẹ woli, tabi on jẹ ẹniti o li ẹmí, jẹ ki nkan wọnyi ti mo kọ si nyin ki o ye e daju pe ofin Oluwa ni nwọn. Ṣugbọn bi ẹnikan ba jẹ òpe, ẹ jẹ ki o jẹ òpe. Nitorina, ará, ẹ mã fi itara ṣafẹri lati sọtẹlẹ ki ẹ má si ṣe danilẹkun lati fi ède fọ̀. Ẹ mã ṣe ohun gbogbo tẹyẹtẹyẹ ati lẹsẹlẹsẹ.