Nitorina awọn ahọn jasi àmi kan, kì iṣe fun awọn ti o gbagbọ́, bikoṣe fun awọn alaigbagbọ́: ṣugbọn isọtẹlẹ kì iṣe fun awọn ti kò gbagbọ́, bikoṣe fun awọn ti o gbagbọ́. Njẹ bi gbogbo ijọ ba pejọ si ibi kan, ti gbogbo nwọn si nfi ède fọ̀, bi awọn ti iṣe alailẹkọ́ ati alaigbagbọ́ ba wọle wá, nwọn kì yio ha wipe ẹnyin nṣe wère? Ṣugbọn bi gbogbo nyin ba nsọtẹlẹ, ti ẹnikan ti kò gbagbọ́ tabi ti kò li ẹ̀kọ́ bá wọle wá, gbogbo nyin ni yio fi òye ẹ̀ṣẹ yé e, gbogbo nyin ni yio wadi rẹ̀: Bẹ̃li a si fi aṣiri ọkàn rẹ̀ hàn; bẹ̃li on o si dojubolẹ yio si sin Ọlọrun, yio si sọ pe, nitotọ Ọlọrun mbẹ larin nyin.
Kà I. Kor 14
Feti si I. Kor 14
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Kor 14:22-25
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò