I. Kor 14:2-4

I. Kor 14:2-4 YBCV

Nitori ẹniti nsọ̀rọ li ède aimọ̀, kò bá enia sọ̀rọ bikoṣe Ọlọrun: nitori kò si ẹniti o gbọ; ṣugbọn nipa ti Ẹmí o nsọ ohun ijinlẹ: Ṣugbọn ẹniti nsọtẹlẹ mba awọn enia sọrọ fun imuduro, ati igbiyanju, ati itunu. Ẹniti nsọ̀rọ li ède aimọ̀ nfi ẹsẹ ara rẹ̀ mulẹ; ṣugbọn ẹniti nsọtẹlẹ nfi ẹsẹ ijọ mulẹ.