Ifẹ a mã mu suru, a si mã ṣeun; ifẹ kì iṣe ilara; ifẹ kì isọrọ igberaga, kì ifẹ̀, Kì ihuwa aitọ́, kì iwá ohun ti ara rẹ̀, a kì imu u binu, bẹ̃ni kì igbiro ohun buburu; Kì iyọ̀ si aiṣododo, ṣugbọn a mã yọ̀ ninu otitọ; A mã farada ohun gbogbo, a mã gbà ohun gbogbo gbọ́, a mã reti ohun gbogbo, a mã fàiyarán ohun gbogbo. Ifẹ kì iyẹ̀ lai: ṣugbọn biobaṣepe isọtẹlẹ ni, nwọn ó dopin; biobaṣepe ẹ̀bun ahọn ni, nwọn ó dakẹ; biobaṣepe ìmọ ni, yio di asan. Nitori awa mọ̀ li apakan, awa si nsọtẹlẹ li apakan. Ṣugbọn nigbati eyi ti o pé ba de, eyi ti iṣe ti apakan yio dopin. Nigbati mo wà li ewe, emi a mã sọ̀rọ bi èwe, emi a mã moye bi ewe, emi a mã gbero bi ewe: ṣugbọn nigbati mo di ọkunrin tan, mo fi ìwa ewe silẹ. Nitoripe nisisiyi awa nriran baibai ninu awojiji; ṣugbọn nigbana li ojukoju: nisisiyi mo mọ̀ li apakan; ṣugbọn nigbana li emi ó mọ̀ gẹgẹ bi mo si ti di mimọ̀ pẹlu. Njẹ nisisiyi igbagbọ́, ireti, ati ifẹ mbẹ, awọn mẹta yi: ṣugbọn eyiti o tobi jù ninu wọn ni ifẹ.
Kà I. Kor 13
Feti si I. Kor 13
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Kor 13:4-13
3 Days
Celebrating love goes beyond a particular date; it is a life that constantly reminds others that God's love came to heal, restore, and give us a life that proclaims his goodness. I invite you to navigate a three-day study of what love represents and what it looks like to love others as God intends us to.
4 Days
Seeds, they’re everywhere. Your words, your money, your children and even you, yourself, are a seed! How do these seeds work and why should it matter to us? Let’s see what the Bible has to say and discover how it can apply to our lives in order to bring us closer to God and His purpose for us.
7 Days
Whether we suffer emotional or physical wounds, forgiveness is the cornerstone of the Christian life. Jesus Christ experience all kinds of unfair and unjust treatment, even to the point of a wrongful death. Yet in his final hour, he forgave the mocking thief on the other cross and his executioners.
7 Awọn ọjọ
Ọkàn nínú awọn ọrọ ti an ṣilo julọ ni "Ìfẹ". An tọka sí ní tó fí aimọkan wa hàn. A un fi ìwà inú, ìbálòpọ̀ ati ṣiṣe ifihan ìfẹ dipo rẹ; eleyii tí àwon Olorin, Eléré ati akowe ìfẹ fín ta ọjà wọn. Sugbọn, Ọlọrun (nínú ìṣẹ̀dá ati ìwà) ni ife, àyàfi tia ba ri ifẹ gẹgẹbi Irisi Bibeli a' ṣi jina sí ririn nínú ìfẹ.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò