I. Kor 13:4-10

I. Kor 13:4-10 YBCV

Ifẹ a mã mu suru, a si mã ṣeun; ifẹ kì iṣe ilara; ifẹ kì isọrọ igberaga, kì ifẹ̀, Kì ihuwa aitọ́, kì iwá ohun ti ara rẹ̀, a kì imu u binu, bẹ̃ni kì igbiro ohun buburu; Kì iyọ̀ si aiṣododo, ṣugbọn a mã yọ̀ ninu otitọ; A mã farada ohun gbogbo, a mã gbà ohun gbogbo gbọ́, a mã reti ohun gbogbo, a mã fàiyarán ohun gbogbo. Ifẹ kì iyẹ̀ lai: ṣugbọn biobaṣepe isọtẹlẹ ni, nwọn ó dopin; biobaṣepe ẹ̀bun ahọn ni, nwọn ó dakẹ; biobaṣepe ìmọ ni, yio di asan. Nitori awa mọ̀ li apakan, awa si nsọtẹlẹ li apakan. Ṣugbọn nigbati eyi ti o pé ba de, eyi ti iṣe ti apakan yio dopin.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú I. Kor 13:4-10