I. Kor 12:22-27

I. Kor 12:22-27 YBCV

Ṣugbọn awọn ẹ̀ya ara wọnni ti o dabi ẹnipe nwọn ṣe ailera jù, awọn li a kò le ṣe alaini jù: Ati awọn ẹ̀ya ara wọnni ti awa rò pe nwọn ṣe ailọlá jù, lori wọnyi li awa si nfi ọlá si jù; bẹni ibi aiyẹ wa si ni ẹyẹ lọpọlọpọ jù. Nitoripe awọn ibi ti o li ẹyẹ li ara wa kò fẹ ohun kan: ṣugbọn Ọlọrun ti ṣe ara lọkan, o si fi ọ̀pọlọpọ ọlá fun ibi ti o ṣe alaini: Ki ìyapa ki o máṣe si ninu ara; ṣugbọn ki awọn ẹ̀ya ara ki o le mã ṣe aniyan kanna fun ara wọn. Bi ẹ̀ya kan ba si njìya, gbogbo ẹ̀ya a si jùmọ ba a jìya; tabi bi a ba mbọla fun ẹ̀ya kan, gbogbo ẹ̀ya a jùmọ ba a yọ̀. Njẹ ara Kristi li ẹnyin iṣe, olukuluku nyin si jẹ ẹ̀ya ara rẹ̀.