Ẹ mã ṣe afarawe mi, ani gẹgẹ bi emi ti nṣe afarawe Kristi. Njẹ, ará, mo yìn nyin ti ẹnyin nranti mi ninu ohun gbogbo, ti ẹnyin ti di ẹ̀kọ́ wọnni mu ṣinṣin, ani gẹgẹ bi mo ti fi wọn le nyin lọwọ. Ṣugbọn mo fẹ ki ẹnyin ki o mọ̀ pe, Kristi li ori olukuluku ọkunrin; ori obinrin si li ọkọ rẹ̀; ati ori Kristi si li Ọlọrun. Olukuluku ọkunrin ti ngbadura tabi ti nsọtẹlẹ ti o bo ori rẹ̀, o ṣe alaibọ̀wọ fun ori rẹ̀. Ṣugbọn olukuluku obinrin ti ngbadura tabi ti nsọtẹlẹ li aibò ori rẹ̀, o ṣe alaibọ̀wọ fun ori rẹ̀: nitori ọkanna ni pẹlu ẹniti o fári. Nitori bi obinrin kò ba bo ori, ẹ jẹ ki o rẹ́ irun rẹ̀ pẹlu: ṣugbọn bi o bá ṣepe ohun itiju ni fun obinrin lati rẹ́ irun tabi lati fári rẹ̀, jẹ ki o bò ori.
Kà I. Kor 11
Feti si I. Kor 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Kor 11:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò