Ṣugbọn ọ̀pọlọpọ wọn ni inu Ọlọrun kò dùn si: nitoripe a bì wọn ṣubu li aginjù. Nkan wọnyi si jasi apẹrẹ fun awa, ki awa ki o má bã ṣe ifẹkufẹ ohun buburu, gẹgẹ bi awọn pẹlu ti ṣe ifẹkufẹ. Bẹ̃ni ki ẹnyin ki o má si jẹ abọriṣa, bi awọn miran ninu wọn; bi a ti kọ ọ pe, Awọn enia na joko lati jẹ ati lati mu, nwọn si dide lati ṣire. Bẹ̃ni ki awa ki o máṣe ṣe àgbere gẹgẹ bi awọn miran ninu wọn ti ṣe, ti ẹgbã-mọkanla-le-ẹgbẹrun enia si ṣubu ni ijọ kan. Bẹ̃ni ki awa ki o máṣe dán Oluwa wò, gẹgẹ bi awọn miran ninu wọn ti dán a wò, ti a si fi ejò run wọn. Bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe kùn, gẹgẹ bi awọn miran ninu wọn ti kùn, ti a si ti ọwọ́ oluparun run wọn. Nkan wọnyi si ṣe si wọn bi apẹrẹ fun wa: a si kọwe wọn fun ikilọ̀ awa ẹniti igbẹhin aiye de bá. Nitorina ẹniti o ba rò pe on duro, ki o kiyesara, ki o má ba ṣubu. Kò si idanwò kan ti o ti ibá nyin, bikoṣe irú eyiti o mọ niwọn fun enia: ṣugbọn olododo li Ọlọrun, ẹniti kì yio jẹ ki a dan nyin wò jù bi ẹnyin ti le gbà; ṣugbọn ti yio si ṣe ọna atiyọ pẹlu ninu idanwò na, ki ẹnyin ki o ba le gbà a.
Kà I. Kor 10
Feti si I. Kor 10
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Kor 10:5-13
5 Days
Are you experiencing a wilderness season, finding no water or oasis for your soul? What if this season held the greatest hope of all: to know God’s Presence intimately, authentically, and passionately? This devotional encourages you that this time is not wasted, though some days you feel as if you are going nowhere. Because no matter what terrain you tread, God is journeying with you as Comforter, Life-giver, & Friend.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò