I. Kor 10:31-33

I. Kor 10:31-33 YBCV

Nitorina bi ẹnyin ba njẹ, tabi bi ẹnyin ba nmu, tabi ohunkohun ti ẹnyin ba nṣe, ẹ mã ṣe gbogbo wọn fun ogo Ọlọrun. Ẹ máṣe jẹ́ ohun ikọsẹ, iba ṣe fun awọn Ju, tabi fun awọn Hellene, tabi fun ijọ Ọlọrun: Ani bi emi ti nwù gbogbo enia li ohun gbogbo, laiwá ere ti ara mi, bikoṣe ti ọpọlọpọ, ki a le gbà wọn lã.