I. Kor 10:23-30

I. Kor 10:23-30 YBCV

Ohun gbogbo li o yẹ fun mi, ṣugbọn ki iṣe ohun gbogbo li o li ere; ohun gbogbo li o yẹ fun mi, ṣugbọn kì iṣe ohun gbogbo ni igbé-ni-ró. Ki ẹnikẹni máṣe mã wá ti ara rẹ̀, ṣugbọn ki olukuluku mã wá ire ọmọnikeji rẹ̀. Ohunkohun ti a ba ntà li ọjà ni ki ẹ mã jẹ, laibere ohun kan nitori ẹri-ọkàn. Nitoripe ti Oluwa ni ilẹ ati ẹkún rẹ̀. Bi ọkan ninu awọn ti kò gbagbọ́ ba pè nyin sibi àse, bi ẹnyin ba si fẹ ilọ; ohunkohun ti a ba gbé kalẹ niwaju nyin ni ki ẹ jẹ, laibere ohun kan nitori ẹri-ọkàn. Ṣugbọn bi ẹnikan ba wi fun nyin pe, A ti fi eyi ṣẹbọ, ẹ máṣe jẹ ẹ nitori ẹniti o fi hàn nyin, ati nitori ẹri-ọkàn (nitoripe ti Oluwa ni ilẹ, ati ẹkún rẹ̀): Mo ni, ẹri-ọkàn kì iṣe ti ara rẹ, ṣugbọn ti ẹnikeji rẹ: nitori ẽṣe ti a fi fi ẹri-ọkàn ẹlomiran dá omnira mi lẹjọ? Bi emi bá fi ọpẹ jẹ ẹ, ẽṣe ti a fi nsọ̀rọ mi ni buburu nitori ohun ti emi dupẹ fun?