I. Kor 10:15-17

I. Kor 10:15-17 YBCV

Emi nsọ̀rọ bi ẹnipe fun ọlọgbọn; ẹ gbà eyiti mo wi rò. Ago ibukún ti awa nsure si, ìdapọ ẹ̀jẹ Kristi kọ́ iṣe? Akara ti awa mbù, ìdapọ ara Kristi kọ́ iṣe? Nitoripe awa ti iṣe ọ̀pọlọpọ jasi akara kan, ara kan: nitoripe gbogbo wa li o jumọ npin ninu akara kan nì.