I. Kro 4:9-10

I. Kro 4:9-10 YBCV

Jabesi si ṣe ọlọla jù awọn arakunrin rẹ̀ lọ: iya rẹ̀ si pe orukọ rẹ̀ ni Jabesi, wipe, Nitoriti mo bi i pẹlu ibanujẹ. Jabesi si ké pè Ọlọrun Israeli, wipe, Iwọ iba jẹ bukún mi nitõtọ, ki o si sọ àgbegbe mi di nla, ki ọwọ rẹ ki o si wà pẹlu mi, ati ki iwọ ki o má si jẹ ki emi ri ibi, ki emi má si ri ibinujẹ! Ọlọrun si mu ohun ti o tọrọ ṣẹ.