DAFIDI ọba si wi fun gbogbo ijọ enia pe, Solomoni ọmọ mi, on nikan ti Ọlọrun ti yàn, jẹ ọmọde o si rọ̀, iṣẹ na si tobi: nitori ti ãfin na kì iṣe fun enia, ṣugbọn fun Ọlọrun Oluwa. Ati pẹlu gbogbo ipa mi ni mo ti fi pèse silẹ fun ile Ọlọrun mi, wura fun ohun ti wura, ati fadakà fun ti fadakà, ati idẹ fun ti idẹ, irin fun ti irin, ati igi fun ti igi; okuta oniki ti a o tẹ̀ bọ okuta lati fi ṣe ọṣọ, ati okuta oniruru àwọ, ati oniruru okuta iyebiye, ati okuta marbili li ọ̀pọlọpọ.
Kà I. Kro 29
Feti si I. Kro 29
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Kro 29:1-2
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò