NIGBANA ni Dafidi wipe, Eyi ni ile Oluwa Ọlọrun, eyi si ni pẹpẹ ọrẹ-sisun fun Israeli. Dafidi si paṣẹ lati ko awọn alejo ti mbẹ ni ilẹ Israeli jọ; o si yan awọn agbẹkuta lati gbẹ okuta lati fi kọ́le Ọlọrun. Dafidi si pese irin li ọ̀pọlọpọ fun iṣo fun ilẹkun ẹnu-ọ̀na, ati fun ìde; ati idẹ li ọ̀pọlọpọ li aini iwọn; Igi kedari pẹlu li ainiye: nitori awọn ara Sidoni, ati awọn ti Tire mu ọ̀pọlọpọ igi kedari wá fun Dafidi. Dafidi si wipe, Solomoni ọmọ mi, ọdọmọde ni, o si rọ̀, ile ti a o si kọ́ fun Oluwa, a o si ṣe e tobi jọjọ, fun okiki ati ogo ka gbogbo ilẹ: nitorina emi o pese silẹ fun u. Bẹ̃ni Dafidi si pese silẹ lọ̀pọlọpọ, ki o to kú. Nigbana li o pe Solomoni ọmọ rẹ̀, o si fi aṣẹ fun u lati kọ́le kan fun Oluwa Ọlọrun Israeli. Dafidi si wi fun Solomoni pe, Ọmọ mi, bi o ṣe ti emi ni, o ti wà li ọkàn mi lati kọ́le kan fun orukọ Oluwa Ọlọrun mi: Ṣugbọn ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe, Iwọ ti ta ẹ̀jẹ silẹ li ọ̀pọlọpọ, iwọ si ti ja ogun nlanla: iwọ kò gbọdọ kọ́ ile fun orukọ mi, nitoriti iwọ ta ẹ̀jẹ pipọ̀ silẹ niwaju mi. Kiyesi i, a o bi ọmọ kan fun ọ, ẹniti yio ṣe enia isimi; emi o si fun u ni isimi lọdọ gbogbo awọn ọta rẹ̀ yika kiri: nitori orukọ rẹ̀ yio ma jẹ Solomoni, emi o si fi alafia ati idakẹjẹ fun Israeli li ọjọ aiye rẹ̀.
Kà I. Kro 22
Feti si I. Kro 22
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Kro 22:1-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò