Dafidi si ranṣẹ pè Sadoku ati Abiatari awọn alufa; ati awọn ọmọ Lefi, Urieli, Asaiah, ati Joeli, Ṣemaiah, ati Elieli, ati Aminadabu; O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li olori awọn baba awọn ọmọ Lefi: ẹ ya ara nyin si mimọ́, ẹnyin ati awọn arakunrin nyin, ki ẹnyin ki o le gbé apoti ẹri Oluwa Ọlọrun Israeli gòke lọ si ibi ti mo ti pèse fun u. Nitoriti ẹnyin kò rù u li akọṣe, ni Oluwa Ọlọrun wa fi ṣe ẹ̀ya si wa li ara, nitori awa kò wá a bi o ti yẹ. Bẹ̃ li awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi ya ara wọn si mimọ́ lati gbe apoti ẹri Oluwa Ọlọrun Israeli gòke wá. Awọn ọmọ Lefi si rù apoti ẹri Ọlọrun bi Mose ti pa a li aṣẹ gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, nwọn fi ọpa rù u li ejika wọn. Dafidi si wi fun olori awọn ọmọ Lefi pe ki nwọn yàn awọn arakunrin wọn, awọn akọrin pẹlu ohun èlo orin, psalteri ati duru, ati kimbali; ti ndún kikan ti o si nfi ayọ gbé ohùn soke.
Kà I. Kro 15
Feti si I. Kro 15
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Kro 15:11-16
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò