Nigbati nwọn si de ilẹ ipaka Kidroni, Ussa nà ọwọ rẹ̀ lati di apoti ẹri na mu; nitoriti awọn malu kọsẹ. Ibinu Oluwa si ru si Ussa, o si lù, nibẹ li o si kú niwaju Ọlọrun. Dafidi si binu nitori ti Oluwa ké Ussa kuro: nitorina ni a ṣe pè ibẹ na ni Peres-Ussa titi di oni. Dafidi si bẹ̀ru Ọlọrun li ọjọ na wipe, Emi o ha ṣe mu apoti ẹri Ọlọrun wá sọdọ mi? Bẹ̃ni Dafidi kò mu apoti ẹri na bọ̀ si ọdọ ara rẹ̀ si ilu Dafidi, ṣugbọn o gbé e ya si ile Obed-Edomu ara Gitti. Apoti ẹri Ọlọrun si ba awọn ara ile Obed-Edomu gbe ni ile rẹ̀ li oṣu mẹta. Oluwa si bukún ile Obed-Edomu ati ohun gbogbo ti o ni.
Kà I. Kro 13
Feti si I. Kro 13
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Kro 13:9-14
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò