SAKARAYA 8:16-17

SAKARAYA 8:16-17 YCE

Àwọn nǹkan tí ó yẹ kí ẹ máa ṣe nìyí: ẹ máa bá ara yín sọ òtítọ́, kí ẹ sì máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ nílé ẹjọ́; èyí ni yóo máa mú alaafia wá. Ẹ má máa gbèrò ibi sí ara yín, ẹ má sì fẹ́ràn ìbúra èké, nítorí gbogbo nǹkan wọnyi ni mo kórìíra.”