ROMU 8:4-6

ROMU 8:4-6 YCE

Ọlọrun ṣe èyí kí á lè tẹ̀lé ìlànà Òfin ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, àní àwa tí ìhùwàsí wa kì í ṣe bíi tí ẹni tí ẹran-ara ń lò ṣugbọn bí àwọn ẹni tí Ẹ̀mí ń darí. Nítorí àwọn tí ó ń hùwà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ẹran- ara ń lò a máa lépa ìtẹ́lọ́rùn fún ẹran-ara; ṣugbọn àwọn tí Ẹ̀mí ń darí a máa lépa àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí. Lílépa àwọn nǹkan ti ẹran-ara nìkan a máa yọrí sí ikú, ṣugbọn lílépa àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí a máa fúnni ní ìyè ati alaafia.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú ROMU 8:4-6