ÌFIHÀN 3

3
Iṣẹ́ sí Ìjọ Sadi
1“Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Sadi:
“Ẹni tí ó ní Ẹ̀mí Ọlọrun meje ati ìràwọ̀ meje ní: Mo mọ iṣẹ́ rẹ. O kàn ní orúkọ pé o wà láàyè ni, òkú ni ọ́! 2Jí lójú oorun! Fún àwọn ohun tí ó ṣẹ́kù ní okun, nítorí àwọn náà ń kú lọ. Nítorí n kò rí iṣẹ́ kan tí o ṣe parí níwájú Ọlọrun mi. 3Nítorí náà, ranti ohun tí o ti gbà tí o sì ti gbọ́, ṣe é, kí o sì ronupiwada. Bí o kò bá jí lójú oorun, n óo dé bí olè, o kò sì ní mọ àkókò tí n óo dé bá ọ.#Mat 24:43-44; Luk 12:39-40; Ifi 16:15 4Ṣugbọn o ní àwọn díẹ̀ ninu ìjọ Sadi tí wọn kò fi èérí ba aṣọ wọn jẹ́. Wọn yóo bá mi kẹ́gbẹ́ ninu aṣọ funfun nítorí wọ́n yẹ. 5Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni a óo wọ̀ ní aṣọ funfun bẹ́ẹ̀. N kò ní pa orúkọ rẹ̀ rẹ́ kúrò ninu ìwé ìyè. N óo jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀ níwájú Baba mi ati níwájú àwọn angẹli rẹ̀.#a Eks 32:32-33; O. Daf 69:28; Ifi 20:12; b Mat 10:32; Luk 12:8
6“Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.
Iṣẹ́ sí Ìjọ Filadẹfia
7“Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Filadẹfia pé:
“Ẹni mímọ́ ati olóòótọ́ nì, ẹni tí kọ́kọ́rọ́ Dafidi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, tíí ṣí ìlẹ̀kùn tí ẹnikẹ́ni kò lè tì í, tíí sìí tìlẹ̀kùn tí ẹnikẹ́ni kò lè ṣí i, ó ní:#Ais 22:22; Job 12:14 8Mo mọ iṣẹ́ rẹ. Wò ó! Mo fi ìlẹ̀kùn kan tí ó ṣí sílẹ̀ siwaju rẹ, tí ẹnikẹ́ni kò lè tì. Mo mọ̀ pé agbára rẹ kéré, sibẹ o ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́. O kò sẹ́ orúkọ mi. 9N óo fi àwọn kan láti inú ilé ìpàdé Satani lé ọ lọ́wọ́, àwọn òpùrọ́ tí wọn ń pe ara wọn ní Juu, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì í ṣe Juu. N óo ṣe é tí wọn yóo fi wá sọ́dọ̀ rẹ, wọn yóo foríbalẹ̀ fún ọ, wọn yóo sì mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.#a Ais 49:23; 60:14; b Ais 43:4 10Nítorí o ti fi ìfaradà pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, Èmi náà yóo pa ọ́ mọ́ ní àkókò ìdánwò tí ń bọ̀ wá bá ayé, nígbà tí a óo dán gbogbo àwọn tí ó ń gbé inú ayé wò. 11Mò ń bọ̀ kíákíá. Di ohun tí ń bẹ lọ́wọ́ rẹ mú ṣinṣin, kí ẹnikẹ́ni má baà gba adé rẹ. 12Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni n óo fi ṣe òpó ninu Tẹmpili Ọlọrun mi. Kò ní kúrò níbẹ̀ mọ́. N óo wá kọ orúkọ Ọlọrun mi ati orúkọ mi titun sí i lára, ati ti Jerusalẹmu titun, ìlú Ọlọrun mi, tí ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ láti ọ̀run, láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun mi.#a Ifi 21:2 b Ais 62:2; 65:15
13“Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń bá àwọn ìjọ sọ.
Iṣẹ́ sí Ìjọ Laodikia
14“Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Laodikia pé:
“Ẹni tí ń jẹ́ Amin, olóòótọ́ ati ẹlẹ́rìí òdodo, alákòóso ẹ̀dá Ọlọrun ní#Òwe 8:22 15Mo mọ iṣẹ́ rẹ. Mo mọ̀ pé o kò gbóná, bẹ́ẹ̀ ni o kò tutù. Ninu kí o gbóná tabi kí o tutù, ó yẹ kí o ṣe ọ̀kan. 16Nítorí pé o lọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́ lásán, o kò gbóná, bẹ́ẹ̀ ni o kò tutù, n óo pọ̀ ọ́ jáde lẹ́nu mi. 17Nítorí ò ń sọ pé: Mo lówó, mo lọ́rọ̀. Kò sí ohun tí mo fẹ́ tí n kò ní. O kò mọ̀ pé akúṣẹ̀ẹ́ tí eniyan ń káàánú ni ọ́, òtòṣì afọ́jú tí ó wà ní ìhòòhò. 18Mo dá ọ nímọ̀ràn pé kí o ra wúrà tí wọ́n ti dà ninu iná lọ́wọ́ mi, kí o lè ní ọrọ̀, kí o ra aṣọ funfun kí o fi bora, kí ìtìjú ìhòòhò tí o wà má baà hàn, sì tún ra òògùn ojú, kí o fi sí ojú rẹ kí o lè ríran. 19Àwọn tí mo bá fẹ́ràn ni mò ń bá wí, àwọn ni mò ń tọ́ sọ́nà. Nítorí náà ní ìtara, kí o sì ronupiwada.#Òwe 3:12; Heb 12:6 20Wò ó! Mo dúró ní ẹnu ọ̀nà, mò ń kan ìlẹ̀kùn. Bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ohùn mi, tí ó ṣílẹ̀kùn, n óo wọlé tọ̀ ọ́ lọ, n óo bá a jẹun, òun náà yóo sì bá mi jẹun. 21Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni n óo jẹ́ kí ó jókòó tì mí lórí ìtẹ́ mi, gẹ́gẹ́ bí Èmi náà ti ṣẹgun, tí mo jókòó ti baba mi lórí ìtẹ́ rẹ̀.
22“Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń bá àwọn ìjọ sọ.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÌFIHÀN 3: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa