ORIN DAFIDI 51:3-6

ORIN DAFIDI 51:3-6 YCE

Nítorí mo mọ ibi tí mo ti ṣẹ̀, nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi sì wà níwájú mi. Ìwọ nìkan, àní, ìwọ nìkan ṣoṣo ni mo ṣẹ̀, tí mo ṣe ohun tí ó burú lójú rẹ, kí ẹjọ́ rẹ lè tọ́ nígbà tí o bá ń dájọ́, kí ọkàn rẹ lè mọ́ nígbà tí o bá ń ṣe ìdájọ́. Dájúdájú, ninu àìdára ni a bí mi, ninu ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mi sì lóyún mi. O fẹ́ràn òtítọ́ inú; nítorí náà, kọ́ mi lọ́gbọ́n ní kọ́lọ́fín ọkàn mi.