ORIN DAFIDI 40:1-10

ORIN DAFIDI 40:1-10 YCE

Sùúrù ni mo fi dúró de OLUWA, ó dẹ etí sí mi, ó sì gbọ́ igbe mi. Ó fà mí jáde láti inú ọ̀gbun ìparun, láti inú kòtò tí ó kún fún ẹrọ̀fọ̀; ó gbé mi kalẹ̀ lórí àpáta, ó sì fi ẹsẹ̀ mi tẹlẹ̀. Ó fi orin titun sí mi lẹ́nu, àní, orin ìyìn sí Ọlọrun wa. Ọ̀pọ̀ yóo rí i, ẹ̀rù óo bà wọ́n, wọn óo sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni náà, tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé OLUWA, tí kò bá àwọn onigbeeraga rìn, àwọn tí wọn ti ṣìnà lọ sọ́dọ̀ àwọn oriṣa. OLUWA, Ọlọrun mi, o ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu fún wa, o sì ti ro ọ̀pọ̀ èrò rere kàn wá. Kò sí ẹni tí a lè fi wé ọ; bí mo bá ní kí n máa polongo ohun tí o ṣe, kí n máa ròyìn wọn, wọ́n ju ohun tí eniyan lè kà lọ. O ò fẹ́ ẹbọ, bẹ́ẹ̀ ni o ò fẹ́ ọrẹ, ṣugbọn o là mí ní etí; o ò bèèrè ẹbọ sísun tabi ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Nígbà náà ni mo wí pé, “Wò ó, mo dé; a ti kọ nípa mi sinu ìwé pé: mo gbádùn láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọrun mi; mo sì ń pa òfin rẹ mọ́ ninu ọkàn mi.” Mo ti ròyìn òdodo ninu àwùjọ ńlá. Wò ó, OLUWA n kò pa ẹnu mi mọ́, gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀. Èmi kò fi ìròyìn ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà rẹ pamọ́. Mo sọ̀rọ̀ òtítọ́ ati ìgbàlà rẹ; n kò dákẹ́ lẹ́nu nípa òtítọ́ ati ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ninu àwùjọ ńlá.