ORIN DAFIDI 37:5-7

ORIN DAFIDI 37:5-7 YCE

Fi ọ̀nà rẹ lé OLUWA lọ́wọ́; gbẹ́kẹ̀lé e, yóo sì ṣe ohun tí ó yẹ. Yóo mú kí ìdáláre rẹ tàn bí ìmọ́lẹ̀; ẹ̀tọ́ rẹ yóo sì hàn kedere bí ọ̀sán gangan. Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLUWA; fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé e. Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí ẹni tí nǹkan ń dára fún; tabi nítorí ẹni tí ń gbèrò ibi, tí ó sì ń ṣe é.