ORIN DAFIDI 18:30-36

ORIN DAFIDI 18:30-36 YCE

Ní ti Ọlọrun, ọ̀nà rẹ̀ pé, pípé ni ọ̀rọ̀ OLUWA; òun sì ni ààbò fún gbogbo àwọn tí ó sá di í. Ta tún ni Ọlọrun, bíkòṣe OLUWA? Àbí, ta ni àpáta, àfi Ọlọrun wa? Ọlọrun tí ó gbé agbára wọ̀ mí, tí ó sì mú ọ̀nà mi pé. Ó fi eré sí mi lẹ́sẹ̀ bíi ti àgbọ̀nrín, ó sì fún mi ní ààbò ní ibi ìsásí. Ó kọ́ mi ní ogun jíjà tóbẹ́ẹ̀ tí mo fi lè fa ọrun idẹ. O ti fún mi ní asà ìgbàlà rẹ, ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ó gbé mi ró, ìrànlọ́wọ́ rẹ sì ni ó sọ mí di ẹni ńlá. O la ọ̀nà tí ó gbòòrò fún mi, n kò sì fi ẹsẹ̀ rọ́.