OLUWA, o ti yẹ̀ mí wò, o sì mọ̀ mí. O mọ ìgbà tí mo jókòó, ati ìgbà tí mo dìde; o mọ èrò ọkàn mi láti òkèèrè réré. O yẹ ìrìn ẹsẹ̀ mi ati àbọ̀sinmi mi wò; gbogbo ọ̀nà mi ni o sì mọ̀. Kódà kí n tó sọ ọ̀rọ̀ jáde lẹ́nu, OLUWA, o ti mọ gbogbo nǹkan tí mo fẹ́ sọ patapata. O pa mí mọ́, níwájú ati lẹ́yìn; o gbé ọwọ́ ààbò rẹ lé mi. Irú ìmọ̀ yìí jẹ́ ohun ìyanu fún mi, ó ga jù, ojú mi kò tó o. Níbo ni mo lè sá lọ, tí ẹ̀mí rẹ kò ní sí níbẹ̀? Níbo ni mo lè sá gbà tí ojú rẹ kò ní tó mi? Ǹ báà gòkè re ọ̀run, o wà níbẹ̀! Bí mo sì tẹ́ ibùsùn mi sí isà òkú, n óo bá ọ níbẹ̀. Ǹ báà hu ìyẹ́, kí n fò lọ sí ibi ojúmọ́ ti ń mọ́ wá, kí n lọ pàgọ́ sí ibi tí òkun pin sí, níbẹ̀ gan-an, ọwọ́ rẹ ni yóo máa tọ́ mi, tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóo sì dì mí mú.
Kà ORIN DAFIDI 139
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ORIN DAFIDI 139:1-10
3 days
God has gone before us and protects us from behind. He has our battles already handled. He has the blindside covered. He isn’t surprised by curveballs. This focused 3-day devotional will leave you encouraged in the truth that God is the provider of the exact portion, the exact measure, for your life.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò