Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi, fi tinútinú yin orúkọ rẹ̀ mímọ́. Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi, má sì ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀, ẹni tí ó ń dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́, tí ó ń wo gbogbo àrùn rẹ sàn; ẹni tí ó ń yọ ẹ̀mí rẹ kúrò ninu ọ̀fìn, tí ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ati àánú dé ọ ládé. Ẹni tí ó ń fi ohun dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn, tí ó fi ń sọ agbára ìgbà èwe rẹ dọ̀tun bíi ti idì. OLUWA a máa dáni láre a sì máa ṣe ìdájọ́ òdodo fún gbogbo àwọn tí a ni lára. Ó fi ọ̀nà rẹ̀ han Mose, ó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ han àwọn ọmọ Israẹli. Aláàánú ati olóore ni OLUWA, kì í tètè bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀. Kì í fi ìgbà gbogbo báni wí, bẹ́ẹ̀ ni ibinu rẹ̀ kì í pẹ́ títí ayé. Kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa, bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa bí àìdára wa. Nítorí bí ọ̀run ti jìnnà sí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ṣe tóbi tó sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Bí ìlà oòrùn ti jìnnà sí ìwọ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó mú ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa. Bí baba ti máa ń ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA máa ń ṣàánú àwọn tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀.
Kà ORIN DAFIDI 103
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ORIN DAFIDI 103:1-13
5 Days
‘Tis the season to be jolly, but also very busy. Come away for a few moments of rest and worship that will sustain you throughout the merry labors of the season. Based on the book Unwrapping the Names of Jesus: An Advent Devotional , this 5-day devotional reading plan will guide you to receive Jesus’ rest this Christmas by taking moments to remember His goodness, express your neediness, seek His stillness, and trust His faithfulness.
7 Days
What would happen if you woke up and reminded yourself of the Gospel every day? This 7-day devotional seeks to help you do just that! The Gospel not only saves us, it also sustains us throughout our lives. Author and Evangelist Matt Brown has formed this reading plan based on the 30-day devotional book written by Matt Brown and Ryan Skoog.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò