ÌWÉ ÒWE 3:3-8

ÌWÉ ÒWE 3:3-8 YCE

Má jẹ́ kí ìwà ìṣòótọ́ kí ó fi ọ́ sílẹ̀, so àánú ati òtítọ́ mọ́ ọrùn rẹ, kọ wọ́n sí oókan àyà rẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, o óo rí ojurere ati iyì lọ́dọ̀ Ọlọrun ati eniyan. Fi tọkàntọkàn gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, má sì tẹ̀lé ìmọ̀ ara rẹ. Mọ Ọlọrun ní gbogbo ọ̀nà rẹ, yóo sì mú kí ọ̀nà rẹ tọ́. Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ, bẹ̀rù OLUWA, kí o sì yẹra fún ibi. Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, yóo jẹ́ ìwòsàn fún ara rẹ, ati ìtura fún egungun rẹ.