ÌWÉ ÒWE 3:1-26

ÌWÉ ÒWE 3:1-26 YCE

Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ ọ, sì pa òfin mi mọ́ lọ́kàn rẹ, nítorí wọn óo fún ọ ní ẹ̀mí gígùn ati ọpọlọpọ alaafia. Má jẹ́ kí ìwà ìṣòótọ́ kí ó fi ọ́ sílẹ̀, so àánú ati òtítọ́ mọ́ ọrùn rẹ, kọ wọ́n sí oókan àyà rẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, o óo rí ojurere ati iyì lọ́dọ̀ Ọlọrun ati eniyan. Fi tọkàntọkàn gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, má sì tẹ̀lé ìmọ̀ ara rẹ. Mọ Ọlọrun ní gbogbo ọ̀nà rẹ, yóo sì mú kí ọ̀nà rẹ tọ́. Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ, bẹ̀rù OLUWA, kí o sì yẹra fún ibi. Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, yóo jẹ́ ìwòsàn fún ara rẹ, ati ìtura fún egungun rẹ. Fi ohun ìní rẹ bọ̀wọ̀ fún OLUWA pẹlu gbogbo àkọ́so oko rẹ. Nígbà náà ni àká rẹ yóo kún bámúbámú, ìkòkò waini rẹ yóo sì kún àkúnya. Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìtọ́ni OLUWA, má sì ṣe jẹ́ kí ìbáwí rẹ̀ sú ọ. Nítorí ẹni tí OLUWA bá fẹ́ níí báwí gẹ́gẹ́ bí baba tí máa ń bá ọmọ rẹ̀ tí ó bá fẹ́ràn wí. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó wá ọgbọ́n rí, ati ẹni tí ó ní òye. Nítorí èrè rẹ̀ dára ju èrè orí fadaka ati ti wúrà lọ. Ọgbọ́n níye lórí ó ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ, kò sí ohun tí o lè fi wé e, ninu gbogbo ohun tí ọkàn rẹ lè fẹ́. Ẹ̀mí gígùn wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ọrọ̀ ati iyì sì wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀. Ọ̀nà rẹ̀ tura pupọ, alaafia sì ni gbogbo ọ̀nà rẹ̀. Igi ìyè ni fún àwọn tí wọ́n rọ̀ mọ́ ọn, ayọ̀ sì ń bẹ fún àwọn tí wọ́n dì í mú ṣinṣin. Ọgbọ́n ni OLUWA fi fi ìdí ayé sọlẹ̀, òye ni ó sì fi dá ọ̀run. Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni ibú fi ń tú omi jáde, tí ìrì fi ń sẹ̀ láti inú ìkùukùu. Ọmọ mi, di ọgbọ́n tí ó yè kooro ati làákàyè mú, má sì ṣe jẹ́ kí wọn bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ, wọ́n yóo jẹ́ ìyè fún ẹ̀mí rẹ, ati ohun ọ̀ṣọ́ ní ọrùn rẹ. Nígbà náà ni o óo máa rìn láìléwu ati láìkọsẹ̀. Bí o bá jókòó, ẹ̀rù kò ní bà ọ́, bí o bá sùn, oorun yóo máa dùn mọ́ ọ. Má bẹ̀rù àjálù òjijì, tabi ìparun àwọn ẹni ibi, nígbà tí ó bá dé bá ọ, nítorí pé, OLUWA ni igbẹkẹle rẹ, kò sì ní jẹ́ kí o ti ẹsẹ̀ bọ tàkúté.