Nítorí ọgbọ́n yóo wọnú ọkàn rẹ, ìmọ̀ yóo sì tu ẹ̀mí rẹ lára, ọgbọ́n inú yóo máa ṣọ́ ọ, òye yóo sì máa dáàbò bò ọ́, yóo máa gbà ọ́ lọ́wọ́ ibi ṣíṣe, ati lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́tàn, àwọn tí wọ́n ti kọ ọ̀nà òdodo sílẹ̀ tí wọn sì ń rìn ninu òkùnkùn; àwọn tí wọn ń yọ̀ ninu ìwà ibi tí wọ́n sì ní inú dídùn sí ìyapa ibi; àwọn tí ọ̀nà wọn wọ́, tí wọ́n kún fún ìwà àrékérekè. A óo gbà ọ́ lọ́wọ́ obinrin oníṣekúṣe, àní lọ́wọ́ obinrin onírìnkurìn pẹlu ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn rẹ̀. Ẹni tí ó kọ ọkọ àárọ̀ rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì gbàgbé majẹmu Ọlọrun rẹ̀. Ẹni tí ilé rẹ̀ rì sinu ìparun, tí ọ̀nà rẹ̀ sì wà ninu ọ̀fìn isà òkú. Kò sí ẹni tí ó tọ̀ ọ́ lọ, tí ó pada rí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í tún pada sí ọ̀nà ìyè. Nítorí náà, máa rìn ní ọ̀nà àwọn eniyan rere, sì máa bá àwọn olódodo rìn. Nítorí àwọn tí wọ́n dúró ṣinṣin ni wọn yóo máa gbé ilẹ̀ náà, àwọn olóòótọ́ inú ni yóo máa wà níbẹ̀, ṣugbọn a óo pa ẹni ibi run lórí ilẹ̀ náà, a óo sì fa alárèékérekè tu kúrò níbẹ̀.
Kà ÌWÉ ÒWE 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ÌWÉ ÒWE 2:10-22
12 Days
Conversations With God is a joyous immersion into a more intimate prayer life, emphasizing practical ways to hear God's voice. God wants us to enjoy a running conversation with Him all of our lives—a conversation that makes all the difference in direction, relationships, and purpose. This plan is filled with transparent, personal stories about the reaching heart of God. He loves us!
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò