ÌWÉ ÒWE 12:1-9

ÌWÉ ÒWE 12:1-9 YCE

Ẹni tí ó fẹ́ ìtọ́sọ́nà, ó fẹ́ ìmọ̀, ṣugbọn ẹni tí ó kórìíra ìbáwí òmùgọ̀ ni. Eniyan rere a máa ní ojurere lọ́dọ̀ OLUWA, ṣugbọn ẹni tí ń pète ìkà ni yóo dá lẹ́bi. Kò sí ẹni tí ó lè ti ipa ìwà ìkà fi ìdí múlẹ̀, ṣugbọn gbòǹgbò olódodo kò ní fà tu. Obinrin oníwàrere ni adé orí ọkọ rẹ̀, ṣugbọn obinrin tí ń dójúti ọkọ dàbí ọyún inú egungun. Èrò ọkàn olódodo dára, ṣugbọn ẹ̀tàn ni ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú. Ọ̀rọ̀ àwọn eniyan burúkú dàbí ẹni tí ó lúgọ láti pa eniyan, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo a máa gbani là. A bi àwọn eniyan burúkú lulẹ̀, wọ́n sì parun, ṣugbọn ìdílé olódodo yóo dúró gbọningbọnin. À máa ń yin eniyan gẹ́gẹ́ bí ó bá ṣe gbọ́n tó, ṣugbọn ọlọ́kàn àgàbàgebè yóo di ẹni ẹ̀gàn. Mẹ̀kúnnù tí ó ní iṣẹ́, tí ó tún gba ọmọ-ọ̀dọ̀ ó sàn ju ẹni tí ó ń ṣe bí eniyan pataki, ṣugbọn tí kò rí oúnjẹ jẹ lọ.