Ẹni tí ó fẹ́ ìtọ́sọ́nà, ó fẹ́ ìmọ̀,
ṣugbọn ẹni tí ó kórìíra ìbáwí òmùgọ̀ ni.
Eniyan rere a máa ní ojurere lọ́dọ̀ OLUWA,
ṣugbọn ẹni tí ń pète ìkà ni yóo dá lẹ́bi.
Kò sí ẹni tí ó lè ti ipa ìwà ìkà fi ìdí múlẹ̀,
ṣugbọn gbòǹgbò olódodo kò ní fà tu.
Obinrin oníwàrere ni adé orí ọkọ rẹ̀,
ṣugbọn obinrin tí ń dójúti ọkọ dàbí ọyún inú egungun.
Èrò ọkàn olódodo dára,
ṣugbọn ẹ̀tàn ni ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú.
Ọ̀rọ̀ àwọn eniyan burúkú dàbí ẹni tí ó lúgọ láti pa eniyan,
ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo a máa gbani là.
A bi àwọn eniyan burúkú lulẹ̀, wọ́n sì parun,
ṣugbọn ìdílé olódodo yóo dúró gbọningbọnin.
À máa ń yin eniyan gẹ́gẹ́ bí ó bá ṣe gbọ́n tó,
ṣugbọn ọlọ́kàn àgàbàgebè yóo di ẹni ẹ̀gàn.
Mẹ̀kúnnù tí ó ní iṣẹ́, tí ó tún gba ọmọ-ọ̀dọ̀
ó sàn ju ẹni tí ó ń ṣe bí eniyan pataki, ṣugbọn tí kò rí oúnjẹ jẹ lọ.
Olódodo a máa ka ẹ̀mí ẹran ọ̀sìn rẹ̀ sí,
ṣugbọn eniyan burúkú rorò sí tirẹ̀.
Ẹni tí ó bá ń dáko yóo ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ,
ṣugbọn ẹni tí ó bá ń lo àkókò rẹ̀ lórí ohun tí kò lérè, kò lọ́gbọ́n lórí.
Ilé ìṣọ́ àwọn eniyan burúkú yóo di òkítì àlàpà,
ṣugbọn gbòǹgbò eniyan rere a máa fìdí múlẹ̀ sí i.
Ọ̀rọ̀ ẹnu eniyan burúkú a máa mú un bíi tàkúté,
ṣugbọn olódodo a máa bọ́ ninu ìyọnu.
Ọ̀rọ̀ ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa mú ìtẹ́lọ́rùn bá a,
a sì máa jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
Ọ̀nà òmùgọ̀ níí dára lójú tirẹ̀,
ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa fetí sí ìmọ̀ràn.
Bí inú bá ń bí òmùgọ̀, kíá ni gbogbo eniyan yóo mọ̀,
ṣugbọn ọlọ́gbọ́n kìí ka ọ̀rọ̀ àbùkù sí.
Ẹni tí ó bá ń sọ òtítọ́ a máa jẹ́rìí òdodo,
ṣugbọn irọ́ ni ẹlẹ́rìí èké máa ń pa.
Ẹni tí í bá máa ń sọ̀rọ̀ jàbùjàbù láìronú,
ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí kí á fi idà gún eniyan,
ṣugbọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹni wo ọgbẹ́ sàn.
Ọ̀rọ̀ òtítọ́ yóo máa wà títí ayé
ṣugbọn irọ́, fún ìgbà díẹ̀ ni.
Ẹ̀tàn ń bẹ lọ́kàn àwọn tí ń pète ibi,
ṣugbọn àwọn tí ń gbèrò rere ní ayọ̀.
Nǹkan burúkú kò ní ṣẹlẹ̀ sí olódodo,
ṣugbọn eniyan burúkú yóo kún fún ìyọnu.
OLUWA kórìíra ẹni tí ń parọ́,
ṣugbọn inú rẹ̀ dùn sí olóòótọ́.
Ọlọ́gbọ́n a máa fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́,
ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ a máa kéde agọ̀ wọn.
Ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ ni yóo máa jẹ́ olórí,
ṣugbọn ọ̀lẹ ni a óo máa mú ṣiṣẹ́ tipátipá.
Ọ̀pọ̀ ìpayà máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá eniyan,
ṣugbọn ọ̀rọ̀ rere a máa mú inú eniyan dùn.